Àwa kò tíì gba owó ló̩wó̩ e̩niké̩ni – Boss Mustapha
Ìròyìn láti o̩wó̩ Yìnká Àlàbí
Awon igbimo ti ijoba apapo gbe kale lori arun coronavirus ni awon eniyan ti n fi esun inakuna owo kan kaakiri.
Eyi lo mu ki olori ajo naa Ogbeni Boss Mustapha ba awon oniroyin soro. Mustapha ni akowe agba fun ijoba apapo. Ara awon ti won jo wa nibe ni Minisita fun eto ile,Alagba Osagie,Minisita eto asa ati iroyin, Alagba Lai Mohammed ati awon to ku.O ni titi di oni , awon ko tii two gba kobo lowo ijoba apapo tabi awon aladani gege bi awon eniyan kan se n gbee poori enu pe awon ti na owo ilu tan.
O ni orisiirisii atejise ni ajo awon n gba leralera nipa awon to fe je nibe ti won ko mo pe awon ko tii tewo gba kobo lowo enikeni.
Boss Mustapha tun fi asiko naa kilo fun awon eniyan lati ma se fi asiri ile owo won sile fun enikeni. O ni jibiti patapata ni ti enikankan ba beere fun BVN won tabi ona ati wo ile owo won. O ni ki oro won maa lo dabi “eni to n wa ifa ti o ri ofo”.
O tun da awon oniroyin lohun nipa pe ijoba apapo ti gbogbo ile iwosan pa. O ni iro nla ni eyi naa. O ni gbogbo ile iwosan lo wa ni sisi sile pelu gbogbo ibi ti won ti n ta oogun.
Boss Mustapha ni ijoba kan gba awon ara ilu ni imoran lati yera fun ile iwosan bayii. O ni ayafi aisan ti oogun ko ba le wo nile mo nikan ni ki won maa gbe lo si ile iwosan.
O ni ile iwosan lewu lati lo lasiko ti a wa yii fun eni to ba ri ogbon re da. O ni ikilo yii wa fun ki eniyan ma baa gbe ohun ti ko gbe kuro nile lo ile.